Tunde Idiagbon: Ṣé ìlàkàkà rẹ̀ láti paná ìwà ìbàjẹ́ ní Nàìjíríà sèso rere bí?

 


Bi a ba n tọka si awọn ọmọ Yoruba to dantọ, to si jẹ awokọse rere, ọkan pataki ni Ajagunfẹyinti Tunde Idiagbon jẹ.

Nigba aye rẹ, Tunde Idiagbon jẹ ologun to ni igbega titi to fi di igbakeji olori orilẹ-ede Naijiria laye ijọba ologun Buhari-Idiagbon laarin ọdun 1983 si 1985.

Ọgagun yii ni ọpọ eeyan mọ si ẹni ti ko gba gbẹrẹ, onigboya, akikanju ati olotitọ ologun, to korira abẹtẹlẹ, ifiyajẹni ati iwa ibajẹ lorisirisi, eyi to yẹ ki ọpọ ọdọ iwoyi fi ṣe awokọse rere.

Bi itan igbe aye Tunde Idiagbon si ṣe lọ ree, gẹgẹ bi a ṣe ka a loju opo Wikipedia atawọn oju opo itakun agbaye miran:

Ibẹrẹ itan igbe aye Tunde Idiagbon

Ọjọ Kẹrinla oṣu Kẹsan-an ọdun 1943 ni Hassan Dogo ati aya rẹ, Ayisatu iyabeji Idiagbon bi Tunde Abdulbaki Idiagbon sile aye nilu Ilorin, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

Tunde lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ United nilu Ilorin laarin ọdun 1950 si 1952, o tun lọ si alakọbẹrẹ Okesuna ni 1953 si 1957, to si jade iwe mẹwa rẹ ni ile ẹkọ girama ologun laarin ọdun 1958 si 1962.

Idiagbon dara pọ mọ ile ẹkọṣẹ ologun tilẹ Pakistan lọdun 1962, to si gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ ọrọ aje, Economics lọdun 1965.

Bo ṣe de si Naijiria pada lo di adari ọ̀wọ́ kẹrin fun Ileesẹ ologun losu kẹjọ ọdun 1965, to si ni igbega diẹ diẹ siwaju di ọdun 1980, to gba oye Ọgagun, Brigadier General.

Laarin oṣu kẹjọ ọdun 1978 si oṣu Kẹwa ọdun 1979, Idiagbon ni alakoso ologun fun ipinlẹ Borno, lasiko ti Ọgagun Olusegun Obasanjo n dari ilẹ Naijiria bii ologun.

Ipa ti Idiagbon ko lati fi iwa ọmọluabi mulẹ ni Naijiria

Lẹyin ti ijọba ologun Olusegun Obasanjo gbe ijọba silẹ fun oloselu lọdun 1979, ti Shehu Shagari di aarẹ oniruuru iwa ibajẹ lo ti fidi mulẹ ni Naijiria.

Bi awọn oloselu ṣe n ko owo ilu mi, ni wọn n jẹ aye familete ki n tutọ, ti iwa ibajẹ lorisirisi si gogo laarin ọmọ Naijiria pẹlu, ti orilẹ-ede Naijiria si ti wọnu gbese ati ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, ti gbogbo ọjà si gbe owo lori.

Ni asiko yii gan ni awọn alakatakiti ẹlẹṣin Maitatsine n ṣe ọṣẹ nipinlẹ to jẹ Gombe lonii, ti ọpọ ẹmi si n sọnu, bẹẹ ni agbara ijọba Shagari ko ka ọpọ itajẹsilẹ to n waye yika Naijiria.

Nigba to di alẹ ọjọ kọkanlelọgbọn oṣù Kejila ọdun 1983, ijọba ologun gba akoso Naijiria labẹ Ọgagun Muhammadu Buhari, ti Tunde Idiagbon si jẹ igbakeji rẹ.

Nitori ọpọlọ pipe ti Idiagbon ni, iwa ọlaju rẹ ati ikorira iwa ibajẹ ni oniruru ọna, Idiagbon lo ipo rẹ bii igbakeji adari ìjọba ologun lati ri pe iwa ọmọluabi gbilẹ ni Naijiria.

Pẹlu ipinnu ọkan, ọkan akin ati akikanju, Idiagbon ṣe ifilọlẹ eto igbogun tiwa ibajẹ ni Naijiria, ti wọn pe ni War Against Indiscipline (WAI), eyi to wa ni iṣọri marun:

Tunde Idiagbon ati aarẹ Buhari

Ofin WAI onisọri marun ti Idiagbon gbe kalẹ

  • Iṣọri akọkọ ni ofin tito sori ila:

Ofin yii lo pọn ni dandan fun awọn ọmọ Naijiria lati maa to si ori ila nibikibi ti ero ba pọ si, bii ile ifowopamọ, ile ifiweransẹ, ibudo itaja, ibudokọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn ologun ati ikọ ọmọogun WAI si wa nitosi lati fi iya jẹ ẹnikẹni to ba tapa si ofin naa.

Ogunjọ oṣù kẹta ọdun 1984 ni wọn ṣe ifilọlẹ ofin naa.

  • Iṣọri keji ni ofin to de iṣẹ ọba ati ti aladani:

Ofin yii lo n sewuri fun iṣẹ asekara, dide ibi isẹ lakoko ati ikorira asa gbigba abẹtẹlẹ lẹnu isẹ.

Ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o ru awọn ofin yii loju ni iya nla n duro de e.

Koda, oṣiṣẹ ọba to ba pẹ de ibi iṣẹ yoo maa tọ bii ọpọlọ ni tabi ko jẹ koboko Sọja, bii ijiya ẹṣẹ rẹ.

Koda, eyi gan de awọn ọgba ile ẹkọ nitori iwa ọdaran nla ni fun ẹnikẹni lati ṣe magomago lasiko idanwo.

Ọjọ kinni oṣù Karun ọdun 1984 ni wọn ṣe ifilọlẹ rẹ.

  • Iṣọri kẹta ni nini ifẹ Naijiria tọkantọkan:

Ofin yii ni wọn gbe kalẹ lati ṣe koriya fun lilo awọn eroja ta n pese labẹle, eyi ti yoo mu agbega ba awọn Ileesẹ nlanla to wa ni Naijiria.

Bakan naa ni ilana ẹ pada soko wa labẹ ofin yii, eyi to n ṣe iwuri fun eto ọgbin aladanla, ki ounjẹ le pọ yanturu ni Naijiria.

Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1984 ni wọn ṣe ifilọlẹ rẹ
  • Iṣọri kẹrin ni igbogun tiwa ajẹbanu ati didoju ọrọ aje Naijiria bolẹ:

Ofin yii lo n gbogun ti iwa dida owo ilu sapo ara ẹni ati híhu awọn iwa to le ṣe akoba fun ọrọ aje wa.

Ọna lati ṣe aseyọri nidi eyi lo mu ki ijọba ṣe ayipada àwọ̀ owo beba Naijiria, eyi ti yoo ba ọpọ owo ilu tuulu, tawọn oloselu ti di pamọ sinu ile jẹ mọ wọn lọwọ.

Ẹnikẹni to ba si fẹ paarọ owo ni banki kọja ẹgbẹrun marun naira, yoo salaye ibi to ti ri owo ọhun fun ijọba, ki wọn to le fun ni iwe àṣẹ lati paarọ rẹ.

Ọjọ Kerinla oṣù Karun ọdun 1985 si ni wọn ṣe ifilọlẹ rẹ.

  • Iṣọri karun ni ofin imọtoto ayika:

Wọn ṣe ifilọlẹ ofin naa ni ọjọ kọkandinlọgbọn osu keje ọdun 1985.

Ofin yii si lo wa lati ri daju pe ayika wa ni mimọ toni toni, ẹnikẹni ko gbọdọ sọ idọti kaakiri ayika, ọkọ ero kọọkan si lo gbọdọ ni ike idalẹsi.

Ọja, ile ẹkọ, ibudo itaja tabi Ileesẹ ti ayika rẹ ba kun fun ẹgbin ru igi oyin, ti iya nla si n duro de ẹni to ba tako ofin imọtoto ayika.

Awọn eeyan ti ọbẹ ofin WAI ge lọwọ

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n kerora ifilọlẹ awọn ofin to n gbogun ti iwa ibajẹ ti Idiagbon gbe kalẹ nigba naa, nitori o ṣe ajeji lara wọn, to si tun ṣe akoba fun ọna ounjẹ awọn eeyan miran.

Lara awọn eekan ilu ti ọbẹ ofin yii ge lọwọ ni Fela Anikulapo Kuti, ti ọwọ tẹ pe o ko owo ilẹ okeere nla jade lọ soke okun.

Gbogbo aayan rẹ lati salaye bi owo naa ṣe jẹ si lo ja si pabo.

Elomiran ni Oloye MKO Abiola ti ijọba gbe ẹsẹ le beba itẹwe to fẹ ko wọle lati oke okun fun Ileesẹ itẹwe iroyin rẹ.

Igbagbọ Idiagbon ni pe Naijiria yẹ ko le e da duro lati pese awọn eroja ta nilo fun awọn Ileesẹ nla nla wa labẹle.

Asiko ifilọlẹ ofin WAI yii naa ni wọn ju gomina tẹlẹ nipinlẹ Kano, Alhaji Barkin Zuwo si ẹwọn ọtalerugba o din mẹwa ọdun lori iwa ajẹbanu.

Elomiran ti ọbẹ igbogun ti iwa ajẹbanu tun ba nidi ni Umaru Dikko, tii ṣe minisita feto irinna laye ijọba Shagari, ẹni to salọ silu ọba bi ologun ṣe gba ijọba.

Ṣe ni wọn kede rẹ pe, ijọba n wa Dikko lori ẹsun pe o ji biliọnu kan dọla owo Naijiria, ti wọn si gbindanwo lati jí gbe pada wale, amọ ko seese tori ijọba Gẹẹsi doju igbesẹ naa bolẹ.

Bakan naa, ijọba Buhari-Idiagbon ni ki wọn yẹgi fun awọn gbajumọ marun nidi gbigbe oogun oloro, eyi to jẹ ara ọna tawọn eeyan n gba wa owo ojiji lasiko naa.

Orukọ wọn ni Bartholomew Owoh, Bernard Ogedemgbe, Alhaji Akanni Lawal Ojuolape, Sidikatu Tairu ati Ayisat Ajike Muhammed.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo koro oju si iwa ipaniyan yii nigba naa amọ esi ti Idiagbon fọ pada fun wọn ni pe:

"Ojutu àrà ọ̀tọ̀ ni Naijiria nilo lati wagbo dẹkun fun àṣà nini owo kiakia eyi to n ṣe iwuri fun iwa ọdaran."

Ni gbogbo akoko ti ọgagun Idiagbon n ṣíṣẹ lọ yii, ko si ẹnikẹni to pade ẹrin lẹnu rẹ ri nita gbangba nitori kii rẹrin si ohunkohun.

Akoko kan wa ti wọn bi leere pe kí lo de ti kii rẹrin, amọ idahun rẹ ni pe ẹẹkan lọdun lo yẹ ki ologun maa rẹrin.

Ṣugbọn ta ba wo bi Idiagbon ṣe gbe ọrọ Naijiria sori to, to si n lakaka fun orilẹede ti yoo goke agba, ipo ẹyin ti Naijiria wa nigba naa ko to lati pa ẹnikẹni lẹrin lootọ.

Iditẹ gbajọba to yẹ igi mọ Idiagbon nidii

Lasiko ti ijọba Buhari-Idiagbon n lakaka lati fi iwa Ọmọluabi ati ifẹ ilẹ baba ẹni sookan aya ọmọ Naijiria kọọkan, ariwo pe ijọba n ni awọn lara ni ọpọ ọmọ ilẹ yii mu bọ ẹnu.

Amọ awọn ọmọ ologun to n ditẹ gbajọba ati baba ogun wọn bii Ọgagun Sani Abacha, ko laya to bẹẹ lati gbena woju Tunde Idiagbon, tii ṣe igbakeji Buhari nigba naa, lati doju ijọba rẹ bolẹ.

Ṣugbọn wọn n sọ lọwọ lẹsẹ titi to fi lọ fun irinajo hajj lorilẹede Saudi Arabia losu kẹjọ ọdun 1985, ti wọn si doju ijọba Buhari-Idiagbon bolẹ, eyi ti Ọgagun Ibrahim Babangida lewaju rẹ.

Ọdun kan ati oṣu mẹjọ si ni Idiagbon lo lori aga aleefa bii igbakeji adari Naijiria, ki wọn to yẹ aga akoso nidi rẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo gba Idiagbon nimọran pe ko ma pada wa si Naijiria mọ lati Mecca, ti ọba Saudi gan si fun laaye lati duro sibẹ, amọ Idiagbon ko gba.

Gẹgẹ bi akikanju ọmọ Yoruba, o gba pe ibi to ba le, la n ba ọmọkunrin, iwa ojo si ni ki oun duro silẹ okeere, ile baba ọmọ kii sa ba ọmọ lẹru.

Lẹyin ọjọ diẹ, Idiagbon pada si Naijiria, ti ijọba Babangida si fi sinu ahamọ ninu ile nilu Benin ati Bauchi fun ọpọlọpọ osu.

Idiagbon ko ko ọrọ̀ aye jọ lori oye, ko kọle alarinrin, bẹẹ ni ko ka ọkọ ayọkẹlẹ jọ bii ẹkọ. Ko ji owo ilu lati pese fun ọjọ ọla arọmọdọmọ rẹ, ti ko si ja ile onile bo tiẹ lẹyin, bi ọpọ adari wa ti n ṣe.

Ṣugbọn ohun to mumu julọ laya rẹ ni orileede ti yoo ba awujọ agbaye pe ati igbe aye idẹrun fun mutumuwa.

Niwọn igba to jẹ pe awaye ku ko si, Ọgagun Tunde Idiagbon dagbere faye ni ọjọ Kẹrindinlogun oṣu karun ọdun 1999, lasiko aisan ranpẹ ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọta.

Idiagbon tiraka nigba aye rẹ, to si sa ipa rẹ lati jẹ ka ni orile-ede Naijiria to duro rẹ, amọ ọpọ ọmọ Naijiria ta ko o.

Ọpọlọpọ ohun to si korira nigba naa, lo ti wa fẹ oju mọ wa lọwọ ni Naijiria bayii, ti ọkọ Naijiria si n rin loju omi lai mọ ẹni ti yoo ti de ebute ayọ.

Adura wa ni pe ki Ọlọrun tẹ Agagunfẹyinti Tunde Idiagbon si afẹfẹ rere, ko si duro ti ẹbi to fi silẹ.

Bakan la gba ni adura pe, irufẹ orilẹede ti Tunde Idiagbon nla ala pe ki Naijiria jẹ, to si ja fitafita fun, Ọlọrun yoo jẹ ko wa si imusẹ.

Ẹkọ ti itan aye Tunde Idiagbon kọ wa

Tunde Idiagbon ati aarẹ Buhari

Ẹkọ akọkọ ta ri ninu itan igbe aye Tunde Idiagbon ni pe, ka ni ẹmi ikora ẹni nijanu, iwa ọmọluabi ati ifẹ ilẹ baba ẹni.

Itan yii tun kọ wa pe ka ni ipinnu ọkan ati ọkan akin lati gbe orilẹede wa goke agba lai naani isoro yowu to le fẹ doju kọ wa.

Bakan naa ni itan yii tun kọ wa pe, ohun aye yoo ba aye lọ, ka mase ko ọrọ aye le aya tabi ji owo ilu nitori ko si ohun ta mu wa saye, ko si ohun ta mu lọ.

Ẹkọ miran ta tun ri kọ ninu itan yii ni pe, igba ko tọ lọ bii orere, aye ko tọ lọ bii ọpa ìbọn, ohun gbogbo fun igba diẹ ni, ka lọ ni suuru ati ipamọra.

    Comments