Fijilanté ṣèṣì yìnbọn pa Sunday ní Ondo, wọ́n ní wọ́n rò pé ẹranko ni!

 


Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii lo mu Sunday ọkọ mi dero ọrun lẹnu iṣẹ rẹ- Folakemi

Kayeefi losu yii jẹ ti Oloogbe Sunday ẹni ọdun mejilelaadọta ti awọn fijilante ṣeeṣi yinbọn pa ni Omi Alafaa ni Ifọn ni ijọba ibilẹ Ọsẹ nipinlẹ Ondo.

Sunday jẹ akọṣẹmọṣẹ to n tun ohun gbogbo to n lo ina mọnamọna ṣe, o dẹ tun maa n fa ina sile tuntun kaakiri gẹgẹ bii ọna ati jẹ atimu.

Iṣẹ akanṣẹ SUBEB ti wọn pee si lo sọ ọ di ero ọrun ni Ondo nigba to lọ yagbẹ laarin oru ti awọn fijilante si ni wọn ṣeeṣi yinbọn fun un.

Aṣẹ lati kọkọ lọ gba iwe lọdọ awọn Ọlọpaa ṣaaju itọju sunday ati aitete ri mọto to maa gbe e lo sile iwosan naa pẹlu ohun to jẹ ko doloogbe.

Gbogbo asiko ti wọn fi n ṣe eyi lati abule lọ si Ifọn, lọ si Ondo, lọ si Akurẹ kun ẹjẹ to n danu lejika Sunday nibi ti ibọn fijilante ti ba a.

Akoroyin ba awọn olugbe abule naa ti ọrọ ṣoju wọn sọrọ ilẹ kun.

Oba Olufọn ti ilu Ifọn naa ṣalaye pe nitori awọn darandaran Fulani to n ji eniyan gbe ni agbegbe naa ni wọn ṣe bẹrẹ fijilante ṣugbọn o ga ni

A fi ki Ọlọrun tu iyawo rẹ Folakemi Orimọla ati ọmọ kan ti Sunday Orimọla fi silẹ ninu ki onikaluku ma si rin arinfẹsẹ si lẹnu iṣẹ oojọ wa.

Source: BBC Yoruba

Comments