Awọn akọroyin ni ipinlẹ Ọyọ naa ti kọ ipakọ si ipade awọn akọroyin ti minisita tẹlẹ lorilẹ-ede Naijiria, Fẹmi Fani Kayọde nilu Ibadan.

 


Awọn to ṣe eto ipade oniroyin naa ti kọkọ rii daju pe iwọnba aṣayan awọn akọroyin ni wọn pe, wọn si fi kun un pe iwọnba awọn ti wọn fi iwe pe nikan lo yọju nibẹ.

Lẹyin o rẹyin, atawọn ti wọn fi iwe pe, atawọn ti wọn ko fi iwe pe lo kọ lati yọju sibi ipade naa.

Lasiko ipade naa ni Ọgbẹni Eyo Charles ti beere lọwọ minisita tẹlẹ ri ọhun pe "ta alo n gbọ bukaata irinkiri rẹ".

Ibeere naa bi Fani-Kayode ninu, eyi to mu ko pe akọroyin naa ni "ọdẹ''. To si sọ fun un pe ko ye e beere iru nkan bẹ ẹ mọ.

"Tẹ ẹ ba gbagbe, mo sọ ninu fidio to lọ kaakiri ayelujara pe, Olori Alufaa, ati Biṣọpu ni mi ninu ijọ Brotherhood of the Cross and Star , nitori naa ni mo ṣe fa gbogbo nkan le Ọlọrun lọwọ."

Comments