Bí ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood lọ́sẹ̀ yìí rèé

 


Funke Akindele-Bello gbe nkan mẹta ṣe lẹẹkanṣoṣo

Ní ilé gbájúgbàja òṣèré Funke Akindele Bello ti gbogbo ènìyàn mọ sí "Jennifa" ohun mẹtalọkan lo jẹyọ níbẹ̀.

Bí ó ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ibi ló n ṣe ajọdun igbéyawo bákan náà lo tún fi yé àwọn ọlólùfẹ́ rẹ pe wọn kú afojusọ́nà, sinima agbélewo rẹ̀ túntun to n bọ.

Iròyìn tó tó wa léti ni pé, gbájúgbajà òṣèré náà ń pinu láti tún gbé atunṣe eré míràn jáde lára ọ̀kan lárá èyí to ṣe tẹ́lẹ to fi di ìlúmọ̀ọ́ká.


Allwell Ademola ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe ayẹyẹ ọdún 35 lẹ́ẹ̀kẹrin báyìí


Gbajugbaja oṣere to tun n kọrin ni Allwell Ademola ni ọpọ eeyan n sọrọ lori ayelujara latari ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlogoji lọdọọdun.

Lati bii ọdun mẹrin sẹyin lo ti n ṣe ayẹyẹ ọdun yii laipaarọ iye ọjọ ori rẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin kan ni ilu Eko ni Allwell ti ṣalaye pe ko si ohun to buru ninu pe oun n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlogoji lọdọọdun.

O ni eyi ko sọ pe ọdun ohun ko yi pada ati pe o yẹ ki awọn eeyan mọ pe awada lati mu inu ara oun dun lo n jẹ ki oun ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun naa nigba gbogbo.

Allwell ni oun kan n se oun to n mu oun dabi ọdọ sii lọdọọdun ni ati pe iyẹn ko sọ pe ẹni ọdun marundinlogoji ṣi ni oun rara.

O fi imoore han si Olorun pe oun ṣi wa laye lasiko ajakalẹ arun Covid 19 yii

Oṣere Allwell Ademola ni oun gbadura pe ọkan awọn oṣere ẹgbẹ oun a tubọ balẹ.

Ati pe ki Olorun mu inu oun dun sii ṣaaju ayẹyẹ ọjọ ibi oun lọdun to m bọ.


Lateef Adedimeji àti Adebimoe Oyebade

Lọ́sẹ̀ yìí bákan náà àwọn tọ́kọtiyawó orí ayéluujara tí wọ́n dá awuyewuye silẹ́ lọ́jọsi lórí asọ igbéyawo ti wọ́n wọ̀ papọ tún ti gbe òmíràn yọ.

Gẹ́gẹ́ bi ìṣe wọ́n àwọn méjèèjì tún wọ ànkoo bii tọkọtiyàwò ti wọ́n sí fọ́n fóto wọ́n ka sórí ayelujara bi ina wẹ́dà.

Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria lo tún ti wa n bere bayii pé, ṣe tọkọtaya ni awọn méjeeji lootọ ni?

Sùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi ǹkan ti ọgbẹ̀ni Adedimeji sọ, ó ni gbígba àdúra ni ńkan ti àwọn ènìyàn ń rí tori ìpólówó ọja ni àwọn ń se.


Comments