Edo election 2020: Ọlọ́pàá méjì kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole, APC ní kìí ṣe ojú lásán

 


Ori ko alaga ana lẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomhole yọ lọjọ Iṣẹgun, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn ọẹọpaa meji ti wọn jẹ ẹṣọ rẹ.

Oshiomhole lo lewaju ikọ ipolongo ibo Pasitọ Osagie Ize-Iyamu gẹgẹ bi gomino ipinlẹ naa lọ si Usen nigba ti ọkọ akẹru kan ya lọ kọlu awọn ọkọ to n ba a kọwọrin lọ sibi ipolongo naa lagbegbe Oluku Junction ni ijọba ibilẹ ila oorun Ariwa ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Adams Oshiomhole fi sita ṣalaye pe ni nnkan bii agogo mejila ọsan ni iṣẹlẹ naa ṣẹ.

Ọkọ tirela naa kọlu ọkan lara awọn ọkọ Toyota Hilux to n ba a kọwọrin lọ silu Usen nibi ti oun ati Pasitọ Ize-Iyamu to jẹ oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC yoo ti ba awọn araalu naa sọrọ lori idi ti wọn fi gbọdọ di ibo wọn fun APC.

Comments