Iberemi Osadebe da Gospel Salvation Christian Church rú lásìkò ìgbéyàwó ní Father's Church ni Eko

 


Okunrin kan da sọọsi ru lasiko isin igbeyawo, o ni oun lo n kọkọ fẹ tẹlẹ

Darudapọ lo bẹ silẹ ninu ijọ Great Salvation Christian Church ti gbogbo eniyan mọ si Father's Church ni agbegbe Ako Aro, Ifako-Ijaye nipinlẹ Eko lọjọ Satide.

Ọkunrin kan to n jẹ Iberemi Osadebe ati ẹbi rẹ ya wọ sọọsi ti wọn ti n seto igbeyawo lọwọ pe eto naa ko le tẹsiwaju.

O ni iyawo ọjọ naa Gloria ti segbeyawo tẹlẹ ati pe Iyawo oun ni o si bi ọmọ fun oun.

Iroyin fi yeni pe, Osadebe ti ṣe igbeyawo ni ilana ti ibilẹ pẹlu Gloria tẹlẹ lẹyin ti wọn bi ọmọ ẹyọ kan.

Okunrin naa wa ṣe aisan fun bi ọdun marun un, eyi si mu ki o ta gboogbo nkan ini rẹ lati ri iwosan gba.

Ọmọ bibi ipinlẹ Imo ni Osadebe, eyi si lo mu ki o tẹsẹ ile bọ ọrọ aisan ti o si gba ilu wọn Isiala Mbano lọ fun itọju.

Iroyin sọ pe ori akete aisan lo wa nigba ti o gbọ pe iyawo rẹ fun ogun ọdun yoo ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin miran lọjọ kọkandinlọgbọn, osu kẹjọ, ọdun 2020.

Ẹni ọdun mẹtalelogoji ohun ni aisan ẹjẹ riru lo ni to si ti ṣe akoba fun isọrọ rẹ.

O pada wa si ilu Eko lọjọ Eti to ku ọla ọjọ igbeyawo to si ti kọkọ lọ agọ ọlọpaa Agbado Station lati fi to wọn leti pe oun yoo da igbeyawo naa ru

Bi o ṣe de ọgba ile ijosin naa ni deede aago mọkanla awọn adari ijọ to mọọ ti bẹẹ pe ko gbagbe ọrọ naa ti osi fariga

Koda iroyin sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ National ni ọkọ iyawo tuntun ti wọn pe orukọ rẹ ni Henry jẹ, ti wọn si pe wọn bakan naa lati wa pẹtu si aawọ ọhun.

Akọroyin Punch ti ayẹyẹ igbeyawo naa soju rẹ salaye pe awọn ile ijọsin naa se atunṣe ranpẹ si ilana eto igbeyawo naa nigba ti wọn ri bi nkan ṣe ri, ati pe o dabi ẹni pe nkan ko ni fararọ.

Wọn bẹrẹ adura kikan pe ki gnogbo ipinu mọndaru ma waye ninu eto isin igbeyawo naa.

Sugbọn bi alufa ṣe fẹ so tọkọtaya pọ bayii ni awọn ẹbi Osadebe mu ori pẹpẹ ijọ gun ti wọn si kede pe obinrin naa ti ni ọkọ tẹlẹ nitori naa wọn ko le so wọn pọ ninu igbeyawo mimọ.

Awọn eleto abo to wa nibẹ gbe wọn jade ni gbogbo rẹ ba di pẹ n tuka nile ijọsin

Wọn kọ wọn o lọ awọn ebi Osadebe duro si enu ilooro sọọsi pe awọn o ni lọ afi ti wọn ba fopin si isopọ

Ninu ọrọ rẹ Osadebe ti ko le sọrọ daada ni Gloria gbẹtin bẹbọ jẹ fun oun, isẹlẹ to waye yii si ja oun laya pupọ.

O ni Ogun odun ni oun fo se ọkọ Gloria a ni ọmọ kan sugbọn iya mi ko fọwọ si ibasepọ wa nitori a kii se ẹya kan naa, a bi ọmọ kan lọdun 2011 nitori mo nifẹ rẹ.

"Igba ti iya mi ku, mo fẹ lo ile fun eto isinku sugbọn iyawo mi ko lati bami lo nitori o ni ni ibi ti oun ti wa eewo ni ki iyawo ti wọn o san nkan ori rě lọ iru iriajo bẹ bakan naa lo kọ lati jẹ ki n mu ọmọ mi

"Nigba ti mo de abule awọn awọn agbaagba ile ba mi wi pe kilode tinmi o fi mu iyawo mi wa gẹgẹ bi akọbi ọkunrin iya mi, wọn bu ẹgbẹrun lona ogoji Naira fun mi gẹgẹ bi owo itanran, lẹyin ti ọrọ itiju yii ṣẹlẹ, mo jẹjẹ lati san nkan ori rẹ."

"Kia ni mo ta ilẹ ti mo ni, ni milionu kan Naira ti mo si fun ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira lati fi pamọ nitori ati san nkan ori rẹ. Lọdun 2017,a lo ọdọ awọn ẹbi rẹ a si san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun din diẹ gẹgẹ bi owo ori ati awọn nkan miran ti wọn gba.

Osadebe to jẹ awako nigba kan ni nigba ti aisan oun bere ni oun lọ ilu awọn fun itoju ti iyawo oun si kọ lati tẹle oun lọ.

O fi kun pe nigba ti oun wa lori akete aisan ni ilu awon ni iyawo oun ke gbajare pe iya n jẹ oun ati ọmọ ti oun si ni ki wọn ba oun ta mọto ti oun fi n ṣiṣẹ ki wọn si ko owo naa fun Gloria ko fi bẹrẹ okoowo ki o le maa san owo ile iwe ọmọ.

Nigba ti mo gbọ pe o fẹ se iyawo mo pe ẹgbọn mi ni abule láti bere boya o mọ nipa. O ni rara sugbọn ninu oșu kẹta, ẹni kan mu iwe wa fun nitori o n se aisan nigba naa oun si fi iwe naa pamọ. O ni igba ti oun wo lẹta naa o jẹ lẹta ikosilẹ lati kootu

Ninu ọrọ rẹ iyawo oludasile ile ijọ ti igbeyawo naa ti waye Ebube Evans salaye pe oun ti mo Gloria ati Osadebe ti pẹ nigba ti wọn wa si ile ijọsin ni nkan bi ọdun meji sẹyin.

O ni nigba ti o ya, Osadebe lo ilu wọn nítorí o se aisan.

Ati jẹ ati mu soro dun Gloria de bi pe o lọn tọrọ bara ni Ọgba, a ma sọfun awọn eeeyan pe oun nilo owo mọto lọ si ibi ti oun n gbe ni Ekiti, owo yii, wọn salaye pe ọkọ rẹ lo lati mu oniruuru imukjmu ati Siga.

Oya ijo naa fi kun pe, igba ti wọn nile nitori gbese owó ilé ọdun meji, ijọ fun ni yara kan ki o maa gbe.

Gbogbo asiko yii ko si nkankan laarin oun ati ọkọ rẹ, nigba ti o si de pe oun ri ẹni ti o fẹ fẹ, oun mọ pe bukata rẹ yoo kuro lọrun ijọ.

Wọn bẹrẹ igbese bi o ṣe kọ ọkọ rẹ silẹ ile ẹjọ si fun wọn lasẹ lati lọ se igbeyawo wọn

Saaju ni Osadebe ri ta gbogbo nkan ini wọn ni Eko.

Ẹwẹ, ninu iwe ikọsilẹ kootu to tẹ oniroyin lọwọ fi han pe Gloria kọ ọkọ rẹ labẹ ẹsun pe o n muti, siga, ko si itoju ati pe ko si ifẹ laarin awọn mọ.

O ni owo ori ti o san ko ju ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira lọ.

Comments