Kenya Covid-19 fund: Aàrẹ pàṣẹ pé kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó lu owó ìtọ́jú aláìsàn ní póńpó

 


Aarẹ orile-ede Kenya, Uhuru Kenyatta ti paṣẹ ki ileeṣẹ eto ilera ṣe afihan gbogbo iwe to ni i ṣe pẹlu ohun ti wọn ra nipa kikoju ajakalẹ arun Covid-19 ni Kenya.

Aarẹ Uhuru Kenyatta gbe igbesẹ yi lẹyin ti ọrọ jẹyọ pe awọn alaṣẹ kan ji ọpọ miliọnu dọla to yẹ ki wọn fi ra nkan eelo itọju arun Covid-19.

Lara awọn iwe aṣẹ inawo to ni ki wọn gbe jade leleyi ti ileeṣẹ to n pese eelo itọju alaisan ni Kenya, Kenya Medical Supplies Agency fi ra nkan.

Ileeṣẹ yi gan an ni wọn ni magomago ti waye nipa owo to yẹ ki wọn fi ra nkan eloo itọju alarun Covid-19.

Lasiko to n ba awọn Gomina ipinlẹ sọrọ ni Aarẹ Uhuru kede ọrọ yi.

Uhuru ni ''Ileeṣẹ ilera gbọdọ ṣe afihan ọna igbowojade ti ko lẹja n bakan ninu jade laarin ọgbọn ọjọ eyi ti gbogbo eeyan yoo ri loju opo ayelujara''

Awọn alaṣẹ ti wọn fi ẹsun yi kan sọ pe awọn ko mọwọ mẹsẹ.

Comments