Sinimá àwòdamiẹnu: Awọn aṣẹ́wó dín dùǹdú ìyà fún Ẹ̀fáńjẹ́líìsì ní àbẹ́tẹ̀ wọn ní Ejigbo

 


Ẹ wa wo sinima lorita o!

Awọn aṣẹwo ti lu efanjẹliisi daku lÉjigbo nilu Eko o, Wọn ni o kọja aye rẹ nipa wiwaasu ni ile aṣẹwo awọn.

Ẹfanjẹliisi Mathew yii ni wọn ni pe o n pariwo 'ẹ yi pada kuro ninu gbogbo iwa ọwọ yin'

Gẹgẹ bi ọrọ ti ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ, wahala naa bẹrẹ nigba ti ẹfanjẹliisi naa duro niwaju ilumọọka ile itura kan to wa ni Ejigbo to si bẹrẹ iwaasu fun awọn olowo nọọbi naa atawọn onibara wọn pe ki wọn fi awọn iwa ẹṣẹ ọwọ wọn gbogbo silẹ.

Ẹfanjẹliisi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Mathew wa pẹlu ileejọsin kan ti awọn eeyan fẹran pupọ ni ilu Ejigbo ni eyi ti ko mọ pe irinajo iwaasu ọjọ naa lee di wahala.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn iwe iroyin abẹle kan sọ, ọpọ igba atẹyinwa ni wọn ti ṣekilọ fun un pe ko jinna si agbegbe ti wọn ti n na owo wọn nigbakugba to ba ti n waasu.

Ni ọjọ ti a n wi yii, wọn lu ẹfanjẹliisi naa debi pe o daku.

Aladugbo miran ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti yoo waasu wa si ile itura naa,

Ṣugbọn kii sunmọ wọn pupọ to bi o ṣe ṣe lọjọ naa.

Ọpọ awọn aladugbo lo sọ pe ni iwoye ti wọn, ẹfanjẹliisi yii kọja aye rẹ nitori pe "oun funra rẹ mọ pe ibi aimọ ni agbegbe naa" ni Ejigbo.

Iya to jẹ ẹfanjẹliisi yii o jẹ bẹmbẹ lọna yidi.

Comments